a picture showing moyo okediji working on his laptop

Fear Not the Storm

Fear Not the Storm

Àwa kò bẹ̀rù (We are not afraid)

Àyà kò fò wá (Scared are we not)

Olódùmarè lalákǒso (The Almighty is in charge)

sí bí ìjì náà ṣe lè tó (However wild the storm may rage)

Àwa ọmọ Irúnmọlẹ̀ (We are the children of Divine forces)

Ẹ má ṣe bẹ̀rù (Do not be afraid)

Ẹ má ṣe fòyà (Do not nurse any fear)

Nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wa (Because our lord resides with us)

Ibikíbi tí wàhálà lè wà (Wherever the difficulty may arise)

Àwa ọmọ Odùduwà (We are the children of Oduduwa)

Ìlérí tí àwọn baba wá ṣe ni (The promise that our ancestors gave us)

Wípé a ó dé ilẹ̀ ìlérí (That we shall reach our promised land)

Kò sí bí ilẹ̀ náà lè jìn tó (However distant the destination may be)

Àwa ọmọ Atóbijù (We the descendants of the Highest Power)

Ẹ má ṣe fòyà (Do not be afraid)

Ẹ má sà sẹ́hìn (Do not hide behind)

Nítorí Olúwa wà pẹ̀lú wa (Because our lord resides with us)

Kò sí bí ìjì náà ṣe lè tó (However wild the storm may rage)

Àwa ọmọ Irúnmọlẹ̀ (We are the children of Divine forces)

Interested in some of my published works?

Similar Posts

Leave a Reply